20 Jésù dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀lọ̀kọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”
21 Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú bàbá mi ná.”
22 Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé, “Má a tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”
23 Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e.
24 Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì-líle dìde lórí òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jésù ń sùn.
25 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, ‘gbà wá,’ àwa yóò rì.”
26 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. È é se ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú òkun náà wí. gbogbo rẹ̀ sì pa rọ́rọ́.