26 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. È é se ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú òkun náà wí. gbogbo rẹ̀ sì pa rọ́rọ́.
27 Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? kódà ìji-líle àti rírú omi òkun gbọ́ tirẹ̀?”
28 Nígbà ti ó sì dé àpa kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gádárénésì, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí-èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀.
29 Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?”
30 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ̀ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn
31 Àwọn ẹ̀mí-èsú náà bẹ̀ Jésù wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.”
32 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀ kalẹ̀ bèbè-odò bọ́ sínú òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi.