12 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá.
13 Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ bí a ti mọ̀ èyí sí: ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;’ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́sẹ̀.”
14 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èé ṣe tí àwa àti àwọn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”
15 Jésù sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa sọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀.
16 “Kò sí ẹni tí í fi ìrépé aṣọ tutun lẹ ògbólògbó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ.
17 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí titun sínú ògbólògbó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-àwọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-àwọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí titun ni wọn í fi sínú ìgò-àwọ tuntun àwọn méjèèjì a ṣì ṣe dédé.”
18 Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsí i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsìn yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.”