19 Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́,ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni.
20 Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo dàbí fadaka,ṣugbọn èrò ọkàn eniyan burúkú kò já mọ́ nǹkankan.
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa ṣe ọpọlọpọ eniyan ní anfaani,ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan a máa kú nítorí àìgbọ́n.
22 Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là,kì í sì í fi làálàá kún un.
23 Ibi ṣíṣe a máa dùn mọ́ òmùgọ̀,ṣugbọn ìwà ọgbọ́n ni ayọ̀ fún ẹni tí ó mòye.
24 Ohun tí eniyan burúkú ń bẹ̀rù ni yóo dé bá a,ohun tí olódodo ń fẹ́ ni yóo sì rí gbà.
25 Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ,ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae.