18 Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.
19 Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayéṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.
20 Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi,ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀.
21 Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo,ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu.
22 OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́,ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.
23 Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́,ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.
24 Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí,ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá.