11 Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù,ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.
12 Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn,ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.
13 Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun,ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀.
14 Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyèa máa yọni ninu tàkúté ikú.
15 Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere,ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn.
16 Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn.
17 Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala,ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá.