9 Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn,ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.
10 Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà,ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.
11 Ọrọ̀ tí a fi ìkánjú kójọ kì í pẹ́ dínkù,ṣugbọn ẹni tí ó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó ọrọ̀ jọ yóo máa ní àníkún.
12 Bí ìrètí bá pẹ́ jù, a máa kó àárẹ̀ bá ọkàn,ṣugbọn kí á tètè rí ohun tí à ń fẹ́ a máa mú ara yá gágá.
13 Ẹni tí ó kẹ́gàn ìmọ̀ràn yóo parun,ṣugbọn ẹni tí ó bá bẹ̀rù òfin yóo jèrè rẹ̀.
14 Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyèa máa yọni ninu tàkúté ikú.
15 Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere,ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn.