1 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè.
2 Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀.
3 Ojú OLUWA wà níbi gbogbo,ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere.
4 Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́.