6 Má ṣe gbéraga níwájú ọba,tabi kí o jókòó ní ipò àwọn eniyan pataki,
7 nítorí ó sàn kí ó wí fún ọ pé,“Máa bọ̀ lókè níhìn-ín”,jù pé kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ níwájú ọlọ́lá kan lọ.
8 Má fi ìwàǹwára fa ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́,nítorí kí ni o óo ṣe nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́.
9 Bí o bá ń bá aládùúgbò rẹ ṣe àríyànjiyànmá ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn,
10 kí ẹni tí ó bá gbọ́ má baà dójútì ọ́,kí o má baà sọ ara rẹ lórúkọ.
11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ lákòókò tí ó yẹdàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí a gbé sinu àwo fadaka.
12 Ìbáwí ọlọ́gbọ́n dàbí òrùka wúrà,tabi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà ṣe,fún ẹni tí ó ní etí láti fi gbọ́.