8 Má fi ìwàǹwára fa ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́,nítorí kí ni o óo ṣe nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́.
9 Bí o bá ń bá aládùúgbò rẹ ṣe àríyànjiyànmá ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn,
10 kí ẹni tí ó bá gbọ́ má baà dójútì ọ́,kí o má baà sọ ara rẹ lórúkọ.
11 Ọ̀rọ̀ tí a sọ lákòókò tí ó yẹdàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí a gbé sinu àwo fadaka.
12 Ìbáwí ọlọ́gbọ́n dàbí òrùka wúrà,tabi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà ṣe,fún ẹni tí ó ní etí láti fi gbọ́.
13 Bí òtútù yìnyín nígbà ìkórè,bẹ́ẹ̀ ni olóòótọ́ iranṣẹ jẹ́, sí àwọn tí ó rán an,a máa fi ọkàn àwọn oluwa rẹ̀ balẹ̀.
14 Bí òjò tí ó ṣú dudu tí ó fẹ́ atẹ́gùn títíṣugbọn tí kò rọ̀,ni ẹni tí ó ń fọ́nnu láti fúnni lẹ́bùn,tí kò sì fúnni ní nǹkankan.