14 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó ń bẹ̀rù OLUWA nígbà gbogbo,ṣugbọn ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le yóo bọ́ sinu ìyọnu.
15 Ọba burúkú tí ó jọba lórí àwọn talaka,dàbí kinniun tí ń bú ramúramù,tabi ẹranko beari tí inú ń bí.
16 Ìkà, aninilára ni olórí tí kò ní òye,ṣugbọn ẹ̀mí ẹni tí ó bá kórìíra à ń jèrè lọ́nà èrú yóo gùn.
17 Bí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan bá ń da eniyan láàmú,yóo di ìsáǹsá ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,kí ẹnikẹ́ni má ṣe ràn án lọ́wọ́.
18 Ẹni tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú yóo rí ìgbàlà,ṣugbọn ẹni tí ń rìn ségesège yóo ṣubú sinu kòtò.
19 Ẹni tí ń ṣiṣẹ́ oko dáradára, yóo ní oúnjẹ pupọ,ṣugbọn ẹni tí ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò yóo di talaka.
20 Olóòótọ́ yóo ní ibukun lọpọlọpọ,ṣugbọn ẹni tí ń kánjú àtilówó, kò ní lọ láìjìyà.