22 Ahun a máa sáré ati ní ọrọ̀,láìmọ̀ pé òṣì ń bọ̀ wá ta òun.
23 Ẹni tí ó bá eniyan wí,yóo rí ojurere níkẹyìn,ju ẹni tí ń pọ́n eniyan lọ.
24 Ẹni tí ó ja ìyá tabi baba rẹ̀ lólè,tí ó ní, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀”,ẹlẹgbẹ́ apanirun ni.
25 Olójúkòkòrò eniyan a máa dá ìjà sílẹ̀,ṣugbọn ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ṣe rere.
26 Òmùgọ̀ ni ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀,ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn yóo là.
27 Ẹni tí ó ta talaka lọ́rẹ kò ní ṣe aláìní,ṣugbọn ẹni tí ó fojú pamọ́ fún wọn, yóo gba ègún.
28 Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá dìde,àwọn eniyan á sá pamọ́,ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá parun, olódodo á pọ̀ sí i.