11 Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù.
12 Bí aláṣẹ bá ń fetí sí irọ́,gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ yóo di eniyankeniyan.
13 Ohun tí ó sọ talaka ati aninilára di ọ̀kan náà ni pé,OLUWA ló fún àwọn mejeeji ní ojú láti ríran.
14 Ọba tí ó dájọ́ ẹ̀tọ́ fún talaka,ní a óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí.
15 Pàṣán ati ìbáwí a máa kọ́ ọmọ lọ́gbọ́n,ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ yóo dójúti ìyá rẹ̀.
16 Nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè, ẹ̀ṣẹ̀ a máa pọ̀ síi,ṣugbọn lójú olódodo ni wọn yóo ti ṣubú.
17 Tọ́ ọmọ rẹ, yóo sì fún ọ ní ìsinmi,yóo sì mú inú rẹ dùn.