19 ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́,ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan.
20 Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́,má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
21 Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo,kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.
22 Nígbà tí o bá ń lọ, wọn yóo máa tọ́ ọ,bí o bá sùn, wọn yóo máa ṣọ́ ọ,bí o bá jí, wọn yóo máa bá ọ sọ̀rọ̀.
23 Nítorí fìtílà ni òfin,ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè,
24 láti pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obinrin burúkú,ati lọ́wọ́ ẹnu alágbèrè obinrin tí ó dùn lọ́rọ̀.
25 Má jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́,má sì ṣe jẹ́ kí ó fi ìpéǹpéjú rẹ̀ mú ọ.