4 Ó gba gbogbo ìlú olódi Juda títí ó fi dé Jerusalẹmu.
5 Lẹ́yìn náà, wolii Ṣemaaya lọ bá Rehoboamu ati gbogbo àwọn olóyè Juda, tí wọ́n ti péjọ sí Jerusalẹmu lórí ọ̀rọ̀ Ṣiṣaki ọba Ijipti. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA ní ẹ ti kọ òun sílẹ̀, nítorí náà ni òun ṣe fi yín lé Ṣiṣaki lọ́wọ́.”
6 Àwọn ìjòyè ní Israẹli ati Rehoboamu ọba bá wí pẹlu ìtẹríba pé, “Olódodo ni Ọlọrun.”
7 Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti ronupiwada, ó sọ fún wolii Ṣemaaya pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, òun kò ní pa wọ́n run mọ́, ṣugbọn òun óo gbà wọ́n sílẹ̀ díẹ̀. Òun kò ní fi agbára lo Ṣiṣaki láti rọ̀jò ibinu òun sórí Jerusalẹmu.
8 Sibẹsibẹ wọn yóo jẹ́ ẹrú rẹ̀, kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ ninu pé kí wọ́n sin òun OLUWA, ati kí wọ́n sin ìjọba àwọn ilẹ̀ mìíràn.
9 Ṣiṣaki bá gbógun ti Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ìṣúra ilé OLUWA lọ, ati ti ààfin ọba patapata, ati apata wúrà tí Solomoni ṣe.
10 Nítorí náà, Rehoboamu ṣe apata bàbà dípò wọn, ó sì fi wọ́n sábẹ́ àkóso olùṣọ́ ààfin.