1 Ní ọdún kẹrindinlogoji ìjọba Asa, ní ilẹ̀ Juda, Baaṣa ọba Israẹli gbógun ti Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi Rama láti dí ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ Juda, kí ẹnikẹ́ni má baà lè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, kí àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ má sì lè jáde.
2 Nítorí náà, Asa kó fadaka ati wúrà láti ilé ìṣúra ilé OLUWA ati láti ààfin ranṣẹ sí Benhadadi, ọba Siria tí ó ń gbé Damasku, ó ranṣẹ sí i pé:
3 “Jẹ́ kí àjọṣepọ̀ wà láàrin wa gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàrin àwọn baba wa. Fadaka ati wúrà yìí ni mo fi ta ọ́ lọ́rẹ; pa majẹmu tí ó wà láàrin ìwọ ati Baaṣa ọba Israẹli tì, kí ó baà lè kó ogun rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi.”
4 Benhadadi gba ọ̀rọ̀ Asa, ó bá rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jáde láti lọ gbógun ti àwọn ìlú Israẹli. Wọ́n ṣẹgun Ijoni, Dani, Abeli Maimu ati gbogbo ìlú tí wọ́n kó ìṣúra pamọ́ sí ní ilẹ̀ Nafutali.