Kronika Keji 30:1-7 BM

1 Hesekaya ranṣẹ sí gbogbo Juda ati Israẹli. Ó kọ̀wé sí Efuraimu ati Manase pẹlu, pé kí gbogbo wọ́n wá sí ilé OLUWA ní Jerusalẹmu láti wá ṣe Àjọ Ìrékọjá ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli.

2 Ọba, àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan ní Jerusalẹmu ti pinnu láti ṣe àjọ náà ní oṣù keji.

3 Ṣugbọn wọn kò lè ṣe é ní àkókò rẹ̀ nítorí àwọn alufaa tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ kò tíì pọ̀ tó, àwọn eniyan kò sì tíì péjọ sí Jerusalẹmu tán.

4 Ìpinnu yìí dára lójú ọba ati gbogbo ìjọ eniyan.

5 Wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n kéde jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, pé kí àwọn eniyan wá sí Jerusalẹmu láti pa Àjọ Ìrékọjá mọ́ fún OLUWA Ọlọrun Israẹli; nítorí pé wọn kò tíì ṣe Àjọ Ìrékọjá náà pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

6 Àwọn oníṣẹ́ lọ jákèjádò Israẹli ati Juda, pẹlu ìwé láti ọ̀dọ̀ ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba. Wọ́n kọ sinu ìwé náà pé:“Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israẹli, kí ó lè pada sọ́dọ̀ ẹ̀yin tí ẹ kù tí ẹ sá àsálà, tí ọba Asiria kò pa.

7 Ẹ má dàbí àwọn baba yín ati àwọn arakunrin yín tí wọ́n ṣe alaiṣootọ sí OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, tí ó sì sọ ilẹ̀ wọn di ahoro bí ẹ ti rí i yìí.