Kronika Keji 5:8-14 BM

8 Àwọn kerubu na àwọn ìyẹ́ wọn sórí ibi tí àpótí náà wà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bo àpótí náà ati àwọn òpó rẹ̀.

9 Àwọn ọ̀pá náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi lè rí orí wọn láti ibi mímọ́ jùlọ, ṣugbọn wọn kò lè rí wọn láti ìta. Wọ́n wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

10 Ohun kan ṣoṣo tí ó wà ninu àpótí náà ni tabili meji tí Mose kó sibẹ ní òkè Horebu, níbi tí Ọlọrun ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti.

11 Gbogbo àwọn alufaa jáde wá láti ibi mímọ́, (nítorí gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà níbẹ̀ ti ya ara wọn sí mímọ́ láìbèèrè ìpín tí olukuluku wà.

12 Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni, àwọn ọmọkunrin wọn ati àwọn ìbátan wọn dúró ní apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n ń fi ìlù, hapu ati dùùrù kọrin; pẹlu ọgọfa alufaa tí wọ́n ń fi fèrè kọrin,

13 àwọn onífèrè ati àwọn akọrin pa ohùn pọ̀ wọ́n ń kọ orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí OLUWA). Wọ́n ń fi fèrè ati ìlù ati àwọn ohun èlò orin mìíràn kọrin ìyìn sí OLUWA pé:“OLUWA ṣeun,ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ kò lópin.”Ìkùukùu kún inú tẹmpili OLUWA,

14 tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí ògo OLUWA tí ó kún ilé Ọlọrun.