1 WỌNYI li ọ̀rọ ti Mose sọ fun gbogbo Israeli ni ìha ihin Jordani li aginjù, ni pẹtẹlẹ̀ ti o kọjusi Okun Pupa, li agbedemeji Parani, ati Tofeli, ati Labani, ati Haserotu, ati Disahabu.
2 Ijọ́ mọkanla ni lati Horebu wá li ọ̀na òke Seiri dé Kadeṣi-barnea.
3 O si ṣe nigbati o di ogoji ọdún, li oṣù kọkanla, li ọjọ́ kini oṣù na, ni Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fun u li aṣẹ fun wọn;
4 Lẹhin igbati o pa Sihoni tán ọba awọn ọmọ Amori, ti o ngbé Heṣboni, ati Ogu ọba Baṣani, ti o ngbé Aṣtarotu, ni Edrei:
5 Ni ìha ihin Jordani, ni ilẹ Moabu, on ni Mose bẹ̀rẹsi isọ asọye ofin yi, wipe,
6 OLUWA Ọlọrun wa sọ fun wa ni Horebu, wipe, Ẹ gbé ori òke yi pẹ to:
7 Ẹ yipada, ki ẹnyin si mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si lọ si òke awọn ọmọ Amori, ati si gbogbo àgbegbe rẹ̀, ni pẹtẹlẹ̀, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni ìha gusù, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati si Lebanoni, dé odò nla nì, odò Euferate.