1 MOSE si gòke lati pẹtẹlẹ̀ Moabu lọ si òke Nebo, si ori Pisga, ti o dojukọ Jeriko. OLUWA si fi gbogbo ilẹ Gileadi dé Dani hàn a;
2 Ati gbogbo Naftali, ati ilẹ Efraimu, ati ti Manasse, ati gbogbo ilẹ Juda, dé okun ìwọ-õrùn;
3 Ati gusù, ati pẹtẹlẹ̀ afonifoji Jeriko, ilu ọlọpẹ dé Soari.
4 OLUWA si wi fun u pe, Eyi ni ilẹ ti mo bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Emi o fi i fun irú-ọmọ rẹ: emi mu ọ fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ ki yio rekọja lọ sibẹ̀.
5 Bẹ̃ni Mose iranṣẹ OLUWA kú nibẹ̀ ni ilẹ Moabu, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA.
6 O si sin i ninu afonifoji ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Beti-peori; ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o mọ̀ iboji rẹ̀ titi di oni-oloni.
7 Mose si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún nigbati o kú: oju rẹ̀ kò ṣe baìbai, bẹ̃li agbara rẹ̀ kò dinku.
8 Awọn ọmọ Israeli si sọkun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu li ọgbọ̀n ọjọ́: bẹ̃li ọjọ́ ẹkún ati ọ̀fọ Mose pari.
9 Joṣua ọmọ Nuni si kún fun ẹmi ọgbọ́n; nitoripe Mose ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori: awọn ọmọ Israeli si gbà tirẹ̀ gbọ́, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
10 Wolĩ kan kò si hù mọ́ ni Israeli bi Mose, ẹniti OLUWA mọ̀ li ojukoju,
11 Ni gbogbo iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, ti OLUWA rán a lati ṣe ni ilẹ Egipti, si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀;
12 Ati ni gbogbo ọwọ́ agbara, ati ni gbogbo ẹ̀ru nla ti Mose fihàn li oju gbogbo Israeli.