Deu 2 YCE

1 NIGBANA li awa pada, awa si mú ọ̀na wa pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa, bi OLUWA ti sọ fun mi: awa si yi òke Seiri ká li ọjọ́ pupọ̀.

2 OLUWA si sọ fun mi pe,

3 Ẹnyin ti yi òke yi ká pẹ to: ẹ pada si ìha ariwa.

4 Ki iwọ ki o si fi aṣẹ fun awọn enia, pe, Ẹnyin o là ẹkùn awọn arakunrin nyin kọja, awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri; ẹ̀ru nyin yio bà wọn: nitorina ẹ ṣọra nyin gidigidi:

5 Ẹ máṣe bá wọn jà; nitoripe emi ki yio fun nyin ninu ilẹ wọn, ani to bi ẹsẹ̀ kan: nitoriti mo ti fi òke Seiri fun Esau ni iní.

6 Owo ni ki ẹnyin fi rà onjẹ lọwọ wọn, ti ẹnyin o jẹ; owo ni ki ẹnyin si fi rà omi lọwọ wọn pẹlu, ti ẹnyin o mu.

7 Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ ti bukún ọ ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: o ti mọ̀ ìrin rẹ li aginjù nla yi: li ogoji ọdún yi OLUWA Ọlọrun rẹ ti mbẹ pẹlu rẹ; ọdá ohun kan kò dá ọ.

8 Nigbati awa si kọja lẹba awọn arakunrin wa awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, li ọ̀na pẹtẹlẹ̀ lati Elati wá, ati lati Esion-geberi wá, awa pada, awa si kọja li ọ̀na aginjù Moabu.

9 OLUWA si wi fun mi pe, Ẹ máṣe bi awọn ara Moabu ninu, bẹ̃ni ki ẹ máṣe fi ogun jà wọn: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ rẹ̀ fun ọ ni iní; nitoriti mo ti fi Ari fun awọn ọmọ Lotu ni iní.

10 (Awọn Emimu ti ngbé inu rẹ̀ ni ìgba atijọ rí, awọn enia nla, nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki:

11 Ti a nkà kún awọn omirán, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn awọn ara Moabu a ma pè wọn ni Emimu.

12 Awọn ọmọ Hori pẹlu ti ngbé Seiri rí, ṣugbọn awọn ọmọ Esau tẹle wọn, nwọn si run wọn kuro niwaju wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn; gẹgẹ bi Israeli ti ṣe si ilẹ-iní rẹ̀, ti OLUWA fi fun wọn.)

13 Mo ní, Dide nisisiyi, ki ẹ si gòke odò Seredi. Awa si gòke odò Seredi lọ.

14 Ìgba ti awa fi ti Kadeṣi-barnea wá, titi awa fi gòke odò Seredi lọ, o jẹ́ ọgbọ̀n ọdún o le mẹjọ; titi gbogbo iran awọn ologun fi run kuro ninu ibudó, bi OLUWA ti bura fun wọn.

15 Pẹlupẹlu ọwọ́ OLUWA lodi si wọn nitõtọ, lati run wọn kuro ninu ibudó, titi nwọn fi run tán.

16 Bẹ̃li o si ṣe, ti gbogbo awọn ologun nì run, ti nwọn si kú tán ninu awọn enia na,

17 OLUWA si sọ fun mi pe,

18 Iwọ o là ilẹ Ari lọ li oni, li àgbegbe Moabu:

19 Nigbati iwọ ba sunmọtosi awọn ọmọ Ammoni, máṣe bi wọn ninu, bẹ̃ni ki o máṣe bá wọn jà: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ awọn ọmọ Ammoni fun ọ ni iní: nitoriti mo ti fi i fun awọn ọmọ Lotu ni iní.

20 (A si kà eyinì pẹlu si ilẹ awọn omirán; awọn omirán ti ngbé inu rẹ̀ rí; awọn ọmọ Ammoni a si ma pè wọn ni Samsummimu.

21 Awọn enia nla, ti nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn OLUWA run wọn niwaju wọn; nwọn si tẹle wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn;

22 Bi o ti ṣe fun awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, nigbati o run awọn ọmọ Hori kuro niwaju wọn; ti nwọn si tẹle wọn, ti nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn titi di oni-oloni:

23 Ati awọn ọmọ Affimu ti ngbé awọn ileto, titi dé Gasa, awọn ọmọ Kaftori, ti o ti ọdọ Kaftori wá, run wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn.)

24 Ẹ dide, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si gòke odò Arnoni: wò o, emi fi Sihoni ọmọ Amori, ọba Heṣboni lé ọ lọwọ, ati ilẹ rẹ̀: bẹ̀rẹsi gbà a, ki o si bá a jagun.

25 Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi fi ìfoya rẹ, ati ẹ̀ru rẹ sara awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni gbogbo abẹ ọrun, ti yio gburó rẹ, ti yio si warìri, ti yio si ṣe ipàiya nitori rẹ.

Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Sihoni Ọba

26 Mo si rán onṣẹ lati aginjù Kedemotu lọ sọdọ Sihoni ọba Heṣboni pẹlu ọ̀rọ alafia, wipe,

27 Jẹ ki emi ki o là ilẹ rẹ kọja lọ: ọ̀na opópo li emi o gbà, emi ki yio yà si ọtún tabi si òsi.

28 Pẹlu owo ni ki iwọ ki o tà onjẹ fun mi, ki emi ki o jẹ; pẹlu owo ni ki iwọ ki o si fun mi li omi, ki emi ki o mu: kìki ki nsá fi ẹsẹ̀ mi kọja;

29 Bi awọn ọmọ Esau ti ngbé Seiri, ati awọn ara Moabu ti ngbé Ari, ti ṣe si mi; titi emi o fi gòke Jordani si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa.

30 Ṣugbọn Sihoni ọba Heṣboni kò jẹ ki a kọja lẹba on: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mu u li àiya le, o sọ ọkàn rẹ̀ di agídi, ki o le fi on lé ọ lọwọ, bi o ti ri li oni yi.

31 OLUWA si sọ fun mi pe, Wò o, emi ti bẹ̀rẹsi fi Sihoni ati ilẹ rẹ̀ fun ọ niwaju rẹ: bẹ̀rẹsi gbà a, ki iwọ ki o le ní ilẹ rẹ̀.

32 Nigbana ni Sihoni jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Jahasi.

33 OLUWA Ọlọrun si fi i lé wa lọwọ niwaju wa; awa si kọlù u, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀.

34 Awa si kó gbogbo ilu rẹ̀ ni ìgba na, awa si run awọn ọkunrin patapata, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ, ni gbogbo ilu; awa kò jẹ ki ọkan ki o kù:

35 Kìki ohunọ̀sin li a kó ni ikogun fun ara wa, ati ikogun ilu wọnni ti awa kó.

36 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati lati ilu ni lọ ti mbẹ lẹba afonifoji nì, ani dé Gileadi, kò sí ilu kan ti o le jù fun wa: OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn fun wa:

37 Kìki ilẹ awọn ọmọ Ammoni ni iwọ kò sunmọ, tabi ibikibi lẹba odò Jaboku, tabi ilu òke wọnni, tabi ibikibi ti OLUWA Ọlọrun wa kọ̀ fun wa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34