1 AWỌN alufa, awọn ọmọ Lefi, ani gbogbo ẹ̀ya Lefi, ki yio ní ipín tabi iní pẹlu Israeli: ki nwọn ki o ma jẹ ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ati iní rẹ̀ ni ki nwọn ki o ma jẹ.
2 Nitorina ni nwọn ki yio ṣe ni iní lãrin awọn arakunrin wọn: OLUWA ni iní wọn, bi o ti wi fun wọn.
3 Eyi ni yio si ma jẹ́ ipín awọn alufa lati ọdọ awọn enia wá, lati ọdọ awọn ti o ru ẹbọ, iba ṣe akọ-malu tabi agutan, ki nwọn ki o si fi apa fun alufa, ati ẹrẹkẹ mejeji ati àpo.
4 Akọ́so ọkà rẹ pẹlu, ati ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́rẹ irun agutan rẹ, ni ki iwọ ki o fi fun u.
5 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ li o yàn a ninu gbogbo awọn ẹ̀ya rẹ, lati ma duro ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai.
6 Ati bi ọmọ Lefi kan ba ti inu ibode rẹ kan wá, ni gbogbo Israeli, nibiti o gbé nṣe atipo, ti o si fi gbogbo ifẹ́ inu rẹ̀ wá si ibi ti OLUWA yio yàn;
7 Njẹ ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, bi gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Lefi, ti nduro nibẹ̀ niwaju OLUWA.
8 Ipín kanna ni ki nwọn ki o ma jẹ, làika eyiti o ní nipa tità ogún baba rẹ̀.
9 Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe kọ́ ati ṣe gẹgẹ bi ìwa-irira awọn orilẹ-ède wọnni.
10 Ki a máṣe ri ninu nyin ẹnikan ti nmu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là iná já, tabi ti nfọ̀ afọ̀ṣẹ, tabi alakiyesi-ìgba, tabi aṣefàiya, tabi ajẹ́,
11 Tabi atuju, tabi aba-iwin-gbìmọ, tabi oṣó, tabi abokulò.
12 Nitoripe gbogbo awọn ti nṣe nkan wọnyi irira ni si OLUWA: ati nitori irira wọnyi ni OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn jade kuro niwaju rẹ.
13 Ki iwọ ki o pé lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ.
14 Nitori orilẹ-ède wọnyi ti iwọ o gbà, nwọn fetisi awọn alakiyesi-ìgba, ati si awọn alafọ̀ṣẹ: ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni, OLUWA Ọlọrun rẹ kò gbà fun ọ bẹ̃.
15 OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé wolĩ kan dide fun ọ lãrin rẹ, ninu awọn arakunrin rẹ, bi emi; on ni ki ẹnyin ki o fetisi;
16 Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bère lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ́ ajọ nì, wipe, Máṣe jẹ ki emi tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun mi mọ́, bẹ̃ni ki emi ki o má tun ri iná nla yi mọ́; ki emi ki o mà ba kú.
17 OLUWA si wi fun mi pe, Nwọn wi rere li eyiti nwọn sọ.
18 Emi o gbé wolĩ kan dide fun wọn lãrin awọn arakunrin wọn, bi iwọ; emi o si fi ọ̀rọ mi si i li ẹnu, on o si sọ fun wọn gbogbo eyiti mo palaṣẹ.
19 Yio si ṣe, ẹniti kò ba fetisi ọ̀rọ mi ti on o ma sọ li orukọ mi, emi o bère lọwọ rẹ̀.
20 Ṣugbọn wolĩ na, ti o kùgbu sọ ọ̀rọ kan li orukọ mi, ti emi kò fi fun u li aṣẹ lati sọ, tabi ti o sọ̀rọ li orukọ ọlọrun miran, ani wolĩ na yio kú.
21 Bi iwọ ba si wi li ọkàn rẹ pe, Bawo li awa o ṣe mọ̀ ọ̀rọ ti OLUWA kò sọ?
22 Nigbati wolĩ kan ba sọ̀rọ li orukọ OLUWA, bi ohun na kò ba ri bẹ̃, ti kò ba si ṣẹ, eyinì li ohun ti OLUWA kò sọ: wolĩ na li o fi ikùgbu sọ̀rọ: ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru rẹ̀.