1 NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà a, ti o ba lé orilẹ-ède pupọ̀ kuro niwaju rẹ, awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, orilẹ-ède meje, ti o pọ̀ ti o si lagbara jù ọ lọ;
2 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si kọlù wọn; ki o si run wọn patapata; iwọ kò gbọdọ bá wọn dá majẹmu, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn:
3 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá wọn dá ana; ọmọbinrin rẹ ni iwọ kò gbọdọ fi fun ọmọkunrin rẹ̀, ati ọmọbinrin rẹ̀ ni iwọ kò gbọdọ mú fun ọmọkunrin rẹ.
4 Nitoripe nwọn o yi ọmọkunrin rẹ pada lati ma tọ̀ mi lẹhin, ki nwọn ki o le ma sìn ọlọrun miran: ibinu OLUWA o si rú si nyin, on a si run ọ lojiji.
5 Ṣugbọn bayi li ẹnyin o fi wọn ṣe; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn, ẹ o si bì ọwọ̀n wọn lulẹ, ẹ o si ke igbo oriṣa wọn lulẹ, ẹ o si fi iná jó gbogbo ere finfin wọn.
6 Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ: OLUWA Ọlọrun rẹ ti yàn ọ lati jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ.
7 OLUWA kò fi ifẹ́ rẹ̀ si nyin lara, bẹ̃ni kò yàn nyin, nitoriti ẹnyin pọ̀ ni iye jù awọn enia kan lọ; nitoripe ẹnyin li o tilẹ kére jù ninu gbogbo enia:
8 Ṣugbọn nitoriti OLUWA fẹ́ nyin, ati nitoriti on fẹ́ pa ara ti o ti bú fun awọn baba nyin mọ́, ni OLUWA ṣe fi ọwọ́ agbara mú nyin jade, o si rà nyin pada kuro li oko-ẹrú, kuro li ọwọ́ Farao ọba Egipti.
9 Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mọ́ ati ãnu fun awọn ti o fẹ́ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹrun iran;
10 Ti o si nsan a pada fun awọn ti o korira rẹ̀ li oju wọn, lati run wọn: on ki yio jafara fun ẹniti o korira rẹ̀, on o san a fun u loju rẹ̀.
11 Nitorina ki iwọ ki o pa ofin, ati ìlana, ati idajọ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe wọn.
12 Yio si ṣe, nitoriti ẹnyin fetisi idajọ wọnyi, ti ẹ si npa wọn mọ́, ti ẹ si nṣe wọn, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio ma pa majẹmu ati ãnu mọ́ fun ọ, ti o ti bura fun awọn baba rẹ:
13 On o si fẹ́ ọ, yio si bukún ọ, yio si mu ọ bisi i: on o si bukún ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ, ibisi malu rẹ, ati awọn ọmọ agbo-agutan rẹ, ni ilẹ na ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ.
14 Iwọ o jẹ́ ẹni ibukún jù gbogbo enia lọ: ki yio sí akọ tabi abo ninu nyin ti yio yàgan, tabi ninu ohunọ̀sin nyin.
15 OLUWA yio si gbà àrun gbogbo kuro lọdọ rẹ, ki yio si fi ọkan ninu àrun buburu Egipti, ti iwọ mọ̀, si ọ lara, ṣugbọn on o fi wọn lé ara gbogbo awọn ti o korira rẹ.
16 Iwọ o si run gbogbo awọn enia ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi fun ọ; oju rẹ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn awọn oriṣa wọn; nitoripe idẹkùn li eyinì yio jẹ́ fun ọ.
17 Bi iwọ ba wi li ọkàn rẹ pe, Awọn orilẹ-ède wọnyi pọ̀ jù mi lọ; bawo li emi o ṣe le lé wọn jade?
18 Ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru wọn: ṣugbọn ki iwọ ki o ranti daradara ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Farao, ati si gbogbo Egipti;
19 Idanwò nla ti oju rẹ ri, ati àmi, ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi mú ọ jade: bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio ṣe si gbogbo awọn enia na ẹ̀ru ẹniti iwọ mbà.
20 Pẹlupẹlu OLUWA Ọlọrun rẹ yio rán agbọ́n sinu wọn, titi awọn ti o kù, ti nwọn si fi ara wọn pamọ́ fun ọ yio fi run.
21 Ki iwọ ki o máṣe fòya wọn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lãrin rẹ, Ọlọrun ti o tobi ti o si lẹrù.
22 OLUWA Ọlọrun rẹ yio tì awọn orilẹ-ède na jade diẹdiẹ niwaju rẹ: ki iwọ ki o máṣe run wọn tán lẹ̃kan, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba pọ̀ si ọ.
23 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi wọn lé ọ lọwọ, yio si fi iparun nla pa wọn run, titi nwọn o fi run.
24 On o si fi awọn ọba wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si pa orukọ wọn run kuro labẹ ọrun: kò sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ, titi iwọ o fi run wọn tán.
25 Ere finfin oriṣa wọn ni ki ẹnyin ki o fi iná jó: iwọ kò gbọdọ ṣe ojukokoro fadakà tabi wurà ti mbẹ lara wọn, bẹ̃ni ki o máṣe mú u fun ara rẹ, ki o má ba di idẹkùn fun ọ; nitoripe ohun irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ:
26 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ mú ohun irira wá sinu ile rẹ, ki iwọ ki o má ba di ẹni ifibú bi rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o korira rẹ̀ patapata, ki iwọ ki o si kà a si ohun irira patapata; nitoripe ohun ìyasọtọ ni.