Deu 13 YCE

1 BI wolĩ kan ba hù lãrin rẹ, tabi alalá kan, ti o si fi àmi tabi iṣẹ́-iyanu kan hàn ọ,

2 Ti àmi na tabi iṣẹ-iyanu na ti o sọ fun ọ ba ṣẹ, wipe, Ẹ jẹ ki a tẹlé ọlọrun miran lẹhin, ti iwọ kò ti mọ̀ rí, ki a si ma sìn wọn;

3 Iwọ kò gbọdọ fetisi ọ̀rọ wolĩ na, tabi alalá na: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ndan nyin wò ni, lati mọ̀ bi ẹnyin ba fi gbogbo àiya nyin, ati gbogbo ọkàn nyin fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin.

4 Lẹhin OLUWA Ọlọrun nyin ni ki ẹnyin ki o ma rìn, on ni ki ẹ si ma bẹ̀ru, ki ẹ si ma pa ofin rẹ̀ mọ́, ki ẹ si ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ki ẹ si ma sìn i, ki ẹ si ma faramọ́ ọ.

5 Ati wolĩ na, tabi alalá na, ni ki ẹnyin ki o pa; nitoriti o ti sẹ ọtẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ti o ti rà nyin kuro li oko-ẹrú, lati tì ọ kuro li oju ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun rẹ filelẹ li aṣẹ fun ọ lati ma rìn ninu rẹ̀. Bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ibi kuro lãrin rẹ.

6 Bi arakunrin rẹ, ọmọ iya rẹ, tabi ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ obinrin, tabi aya õkan-àiya rẹ, tabi ọrẹ́ rẹ, ti o dabi ọkàn ara rẹ, bi o ba tàn ọ ni ìkọkọ, wipe, Jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti iwọ kò mọ̀ rí, iwọ, tabi awọn baba rẹ;

7 Ninu awọn oriṣa awọn enia ti o yi nyin kakiri, ti o sunmọ ọ, tabi ti o jìna si ọ, lati opin ilẹ dé opin ilẹ;

8 Iwọ kò gbọdọ jẹ fun u, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fetisi tirẹ̀; bẹ̃ni ki oju ki o máṣe ro ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe da a si, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe bò o:

9 Ṣugbọn pipa ni ki o pa a; ọwọ́ rẹ ni yio kọ́ wà lara rẹ̀ lati pa a, ati lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia.

10 Ki iwọ ki o si sọ ọ li okuta, ki o kú; nitoriti o nwá ọ̀na lati tì ọ kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú.

11 Gbogbo Israeli yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù ìwabuburu bi irú eyi mọ́ lãrin nyin.

12 Bi iwọ ba gbọ́ ninu ọkan ninu awọn ilu rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ma gbé inu rẹ̀ pe,

13 Awọn ọkunrin kan, awọn ọmọ Beliali, nwọn jade lọ kuro ninu nyin, nwọn si kó awọn ara ilu wọn sẹhin, wipe, Ẹ jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti ẹnyin kò mọ̀ rí.

14 Nigbana ni ki iwọ ki o bère, ki iwọ ki o si ṣe àwari, ki o si bère pẹlẹpẹlẹ; si kiyesi i, bi o ba ṣe otitọ, ti ohun na ba si da nyin loju, pe a ṣe irú nkan irira bẹ̃ ninu nyin;

15 Ki iwọ ki o fi oju idà kọlù awọn ara ilu na nitõtọ, lati run u patapata, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ohunọ̀sin inu rẹ̀, ni ki iwọ ki o fi oju idà pa.

16 Ki iwọ ki o si kó gbogbo ikogun rẹ̀ si ãrin igboro rẹ̀, ki iwọ ki o si fi iná kun ilu na, ati gbogbo ikogun rẹ̀ patapata fun OLUWA Ọlọrun rẹ: ki o si ma jasi òkiti lailai; a ki yio si tun tẹ̀ ẹ dó mọ́.

17 Ki ọkan ninu ohun ìyasọtọ na má si ṣe mọ́ ọ lọwọ; ki OLUWA ki o le yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀, ki o si ma ṣãnu fun ọ, ki o si ma ṣe iyọnu rẹ, ki o si ma mu ọ bisi i, bi o ti bura fun awọn baba rẹ;

18 Nigbati iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ofin rẹ̀ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34