Deu 16 YCE

Àjọ Ìrékọjá

1 IWỌ ma kiyesi oṣù Abibu, ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe li oṣù Abibu ni OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ilẹ Egipti jade wa li oru.

2 Nitorina ki iwọ ki o ma pa ẹran irekọja si OLUWA Ọlọrun rẹ, ninu agbo-ẹran ati ninu ọwọ́-ẹran, ni ibi ti OLUWA yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si.

3 Iwọ kò gbọdọ jẹ àkara wiwu pẹlu rẹ̀; ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu pẹlu rẹ̀, ani onjẹ ipọnju; nitoripe iwọ ti ilẹ Egipti jade wá ni kanjukanju: ki iwọ ki o le ma ranti ọjọ́ ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wa, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo.

4 Ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ li àgbegbe rẹ gbogbo ni ijọ́ meje; bẹ̃ni ki ohun kan ninu ẹran ti iwọ o fi rubọ li ọjọ́ kini li aṣalẹ, ki o máṣe kù di owurọ̀.

5 Ki iwọ ki o máṣe pa ẹran irekọja na ninu ibode rẹ kan, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ:

6 Ṣugbọn bikoṣe ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o pa ẹran irekọja na li aṣalẹ, nigba ìwọ-õrùn, li akokò ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wá.

7 Ki iwọ ki o si sun u, ki iwọ ki o si jẹ ẹ ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn: ki iwọ ki o si pada li owurọ̀, ki o si lọ sinu agọ́ rẹ.

8 Ijọ́ mẹfa ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu: ati ni ijọ́ keje ki ajọ kan ki o wà fun OLUWA Ọlọrun rẹ; ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹ́ kan.

Àjọ̀dún Ìkórè

9 Ọsẹ meje ni ki iwọ ki o kà fun ara rẹ: bẹ̀rẹsi ati kà ọ̀sẹ meje na lati ìgba ti iwọ ba tẹ̀ doje bọ̀ ọkà.

10 Ki iwọ ki o si pa ajọ ọ̀sẹ mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu ọrẹ ifẹ́-atinuwa ọwọ́ rẹ, ti iwọ o fi fun u, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti busi i fun ọ:

11 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ lãrin rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si.

12 Ki iwọ ki o si ma ranti pe, ẹrú ni iwọ ti jẹ́ ni Egipti: ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ṣe ìlana wọnyi.

Àjọ̀dún Àgọ́

13 Ki iwọ ki o si ma pa ajọ agọ́ mọ́ li ọjọ́ meje, lẹhin ìgba ti iwọ ba ṣe ipalẹmọ ilẹ-ipakà rẹ ati ibi-ifunti rẹ.

14 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ajọ rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ.

15 Ijọ́ meje ni ki iwọ ki o fi ṣe ajọ si OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti OLUWA yio yàn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo asunkún rẹ, ati ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, nitorina ki iwọ ki o ma yọ̀ nitõtọ.

16 Lẹ̃mẹta li ọdún ni ki gbogbo awọn ọkunrin rẹ ki o farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn; ni ajọ àkara alaiwu, ati ni ajọ ọ̀sẹ, ati ni ajọ agọ́: ki nwọn ki o má si ṣe ṣánwọ wá iwaju OLUWA:

17 Ki olukuluku ki o mú ọrẹ wá bi agbara rẹ̀ ti to, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ.

Ìlànà nípa Ẹjọ́ Dídá

18 Awọn onidajọ ati awọn ijoye ni ki iwọ ki o fi jẹ ninu ibode rẹ gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, gẹgẹ bi ẹ̀ya rẹ: ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia na li ododo.

19 Iwọ kò gbọdọ lọ́ idajọ; iwọ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju enia: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbà ẹ̀bun; nitoripe ẹ̀bun ni ifọ́ ọlọgbọ́n li oju, on a si yi ọ̀rọ olododo po.

20 Eyiti iṣe ododo patapata ni ki iwọ ki o ma tọ̀ lẹhin, ki iwọ ki o le yè, ki iwọ ki o si ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.

21 Iwọ kò gbọdọ rì igi oriṣa kan sunmọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ o mọ fun ara rẹ.

22 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbé ọwọ̀n kan kalẹ fun ara rẹ: ti OLUWA Ọlọrun rẹ korira.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34