1 YIO si ṣe, nigbati gbogbo nkan wọnyi ba dé bá ọ, ibukún ati egún, ti mo filelẹ niwaju rẹ, ti iwọ o ba si ranti ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si,
2 Ti iwọ ba si yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo;
3 Nigbana ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio yi oko-ẹrú rẹ pada, yio si ṣãnu fun ọ, yio si pada, yio si kó ọ jọ kuro ninu gbogbo orilẹ-ède wọnni nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si.
4 Bi a ba si lé ẹni rẹ kan lọ si ìha opin ọrun, lati ibẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio kó ọ jọ, lati ibẹ̀ ni yio si mú ọ wá:
5 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si mú ọ wá sinu ilẹ na ti awọn baba rẹ ti ní, iwọ o si ní i; on o si ṣe ọ li ore, yio si mu ọ bisi i jù awọn baba rẹ lọ.
6 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si kọ àiya rẹ nilà, ati àiya irú-ọmọ rẹ, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, ki iwọ ki o le yè.
7 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si fi gbogbo egún wọnyi lé awọn ọtá rẹ lori, ati lori awọn ti o korira rẹ, ti nṣe inunibini si ọ.
8 Iwọ o si pada, iwọ o si gbà ohùn OLUWA gbọ́, iwọ o si ma ṣe gbogbo ofin rẹ̀ ti mo palaṣẹ fun ọ li oni.
9 OLUWA Ọlọrun rẹ yio si sọ ọ di pupọ̀ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, fun rere: nitoriti OLUWA yio pada wa yọ̀ sori rẹ fun rere, bi o ti yọ̀ sori awọn baba rẹ:
10 Bi iwọ ba gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́, ti a kọ sinu iwé ofin yi; bi iwọ ba si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ.
11 Nitori aṣẹ yi ti mo pa fun ọ li oni, kò ṣoro jù fun ọ, bẹ̃ni kò jìna rere si ọ.
12 Kò sí li ọrun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio gòke lọ si ọrun fun wa, ti yio si mú u wá fun wa, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e?
13 Bẹ̃ni kò sí ni ìha keji okun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio rekọja okun lọ fun wa, ti yio si mú u fun wa wá, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e?
14 Ṣugbọn ọ̀rọ na li o wà nitosi rẹ girigiri yi, li ẹnu rẹ, ati li àiya rẹ, ki iwọ ki o le ma ṣe e.
15 Wò o, emi fi ìye ati ire, ati ikú ati ibi, siwaju rẹ li oni;
16 Li eyiti mo palaṣẹ fun ọ li oni lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀ mọ́, ki iwọ ki o le yè, ki o si ma bisi i, ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le busi i fun ọ ni ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a.
17 Ṣugbọn bi àiya rẹ ba pada, ti iwọ kò ba si gbọ́, ṣugbọn ti iwọ di ẹni fifà lọ, ti iwọ si mbọ oriṣa, ti iwọ si nsìn wọn;
18 Emi sọ fun nyin li oni, pe ṣiṣegbé li ẹnyin o ṣegbé; ẹnyin ki yio mu ọjọ́ nyin pẹ lori ilẹ, nibiti iwọ ngòke Jordani lọ lati gbà a.
19 Emi pè ọrun ati ilẹ jẹri tì nyin li oni pe, emi fi ìye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn ìye, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irú-ọmọ rẹ:
20 Ki iwọ ki o le ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ki iwọ ki o le ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ati ki iwọ ki o le ma faramọ́ ọ: nitoripe on ni ìye rẹ, ati gigùn ọjọ́ rẹ: ki iwọ ki o le ma gbé inu ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, ati fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn.