Deu 15 YCE

Ọdún Keje

1 LẸHIN ọdún mejemeje ni ki iwọ ki o ma ṣe ijọwọlọwọ.

2 Ọ̀na ijọwọlọwọ na si li eyi: gbogbo onigbese ti o wín ẹnikeji rẹ̀ ni nkan ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ; ki o ma ṣe fi agbara bère rẹ̀ lọwọ ẹnikeji rẹ̀, tabi lọwọ arakunrin rẹ̀; nitoriti a pè e ni ijọwọlọwọ OLUWA.

3 Iwọ le fi agbara bère lọwọ alejò: ṣugbọn eyiti ṣe tirẹ ti mbẹ li ọwọ́ arakunrin rẹ, ni ki iwọ ki o jọwọ rẹ̀ lọwọ.

4 Ṣugbọn ki yio sí talaka ninu nyin; (nitoripe OLUWA yio busi i fun ọ pupọ̀ ni ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati gbà a;)

5 Kìki bi iwọ ba fi ifarabalẹ fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi gbogbo ofin yi, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni lati ṣe.

6 Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ, bi o ti ṣe ileri fun ọ: iwọ o si ma wín ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn iwọ ki yio tọrọ; iwọ o si ma ṣe olori ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn nwọn ki yio ṣe olori rẹ.

7 Bi talakà kan ba mbẹ ninu nyin, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ, ninu ibode rẹ kan, ni ilẹ rẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe mu àiya rẹ le si i, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe há ọwọ́ rẹ si talakà arakunrin rẹ:

8 Sugbọn lilà ni ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun u, ki iwọ ki o si wín i li ọ̀pọlọpọ tó fun ainí rẹ̀, li ohun ti nfẹ́.

9 Ma kiyesara ki ìro buburu kan ki o máṣe sí ninu àiya rẹ, wipe, Ọdún keje, ọdún ijọwọlọwọ sunmọtosi; oju rẹ a si buru si arakunrin rẹ talakà, ti iwọ kò si fun u ni nkan; on a si kigbe pè OLUWA nitori rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ fun ọ.

10 Ki iwọ ki o fi fun u nitõtọ, ki inu rẹ ki o máṣe bàjẹ́ nigbati iwọ ba fi fun u: nitoripe nitori nkan yi ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo iṣẹ rẹ, ati ni gbogbo ohun ti iwọ ba dá ọwọ́ rẹ lé.

11 Nitoripe talakà kò le tán ni ilẹ na: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun arakunrin rẹ, fun talakà rẹ, ati fun alainí rẹ, ninu ilẹ rẹ.

Ìlò Ẹrú

12 Ati bi a ba tà arakunrin rẹ kan fun ọ, ọkunrin Heberu, tabi obinrin Heberu, ti o si sìn ọ li ọdún mẹfa; njẹ li ọdún keje ki iwọ ki o rán a lọ kuro lọdọ rẹ li ominira.

13 Nigbati iwọ ba si nrán a lọ li ominira kuro lọdọ rẹ, iwọ kò gbọdọ jẹ ki o lọ li ọwọ́ ofo:

14 Ki iwọ ki o pèse fun u li ọ̀pọlọpọ lati inu agbo-ẹran rẹ wá, ati lati ilẹ-ipakà rẹ, ati lati ibi ifunti rẹ, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún ọ ni ki iwọ ki o fi fun u.

15 Ki iwọ ki o si ranti pe, iwọ a ti ma ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ: nitorina ni mo ṣe fi aṣẹ nkan yi lelẹ fun ọ li oni.

16 Yio si ṣe, bi o ba wi fun ọ pe, Emi ki yio jade lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o fẹ́ ọ ati ile rẹ, nitoriti o dara fun u lọdọ rẹ;

17 Nigbana ni ki iwọ ki o mú olu kan, ki iwọ ki o si fi lu u li etí mọ́ ara ilẹkun, ki on ki o si ma ṣe ọmọ-ọdọ rẹ lailai. Ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ni ki iwọ ki o ṣe bẹ̃ si gẹgẹ.

18 Ki o máṣe ro ọ loju, nigbati iwọ ba rán a li ominira lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o ní iye lori to alagbaṣe meji ni sísìn ti o sìn ọ li ọdún mẹfa: OLUWA Ọlọrun rẹ yio si busi i fun ọ ninu gbogbo ohun ti iwọ nṣe.

Àkọ́bí Mààlúù ati ti Aguntan

19 Gbogbo akọ́bi akọ ti o ti inu ọwọ-ẹran rẹ ati inu agbo-eran rẹ wá, ni ki iwọ ki o yàsi-mimọ́, fun OLUWA Ọlọrun rẹ: iwọ kò gbọdọ fi akọ́bi ninu akọmalu rẹ ṣe iṣẹ kan, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹrun akọ́bi agutan rẹ,

20 Ki iwọ ki o ma jẹ ẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ọdọdún, ni ibi ti OLUWA yio yàn, iwọ, ati awọn ara ile rẹ.

21 Bi abùku kan ba si wà lara rẹ̀, bi o mukun ni, bi o fọju ni, tabi bi o ni abùku buburu kan, ki iwọ ki o máṣe fi rubọ si OLUWA Ọlọrun rẹ.

22 Ki iwọ ki o jẹ ẹ ninu ibode rẹ: alaimọ́ ati ẹni ti o mọ́ ni ki o jẹ ẹ bakanna, bi esuwo, ati bi agbọnrin.

23 Kìki iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ rẹ̀; ki iwọ ki o dà a silẹ bi omi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34