Deu 31 YCE

Joṣua Gba Ipò Mose

1 MOSE si lọ, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo Israeli.

2 O si wi fun wọn pe, Emi di ẹni ọgọfa ọdún li oni; emi kò le ma jade ki nsi ma wọle mọ́: OLUWA si ti wi fun mi pe, Iwọ ki yio gòke Jordani yi mọ́.

3 OLUWA Ọlọrun rẹ, on ni yio rekọja ṣaju rẹ, on ni yio si run orilẹ-ède wọnyi kuro niwaju rẹ, iwọ o si gbà wọn: ati Joṣua, on ni yio gòke ṣaju rẹ, bi OLUWA ti wi.

4 OLUWA yio si ṣe si wọn bi o ti ṣe si Sihoni ati si Ogu, ọba awọn Amori, ati si ilẹ wọn; awọn ẹniti o run.

5 OLUWA yio si fi wọn tọrẹ niwaju nyin, ki ẹnyin ki o le fi wọn ṣe gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ ti mo pa fun nyin.

6 Ẹ ṣe giri ki ẹ si mu àiya le, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya wọn: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ, on li o mbá ọ lọ; on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ.

7 Mose si pè Joṣua, o si wi fun u li oju gbogbo Israeli pe, Ṣe giri ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio bá awọn enia yi lọ si ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba wọn, lati fi fun wọn; iwọ o si mu wọn gbà a.

8 Ati OLUWA on li o nlọ ṣaju rẹ; on ni yio pẹlu rẹ, on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ: máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ.

Kíka Òfin ní Ọdún Keje-keje

9 Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli.

10 Mose si paṣẹ fun wọn, wipe, Li opin ọdún meje meje li akokò ọdún idasilẹ, ni ajọ agọ́.

11 Nigbati gbogbo Israeli ba wá farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti on o gbé yàn, ki iwọ ki o kà ofin yi niwaju gbogbo Israeli li etí wọn.

12 Kó awọn enia na jọ, awọn ọkunrin ati awọn obinrin ati awọn ọmọde, ati alejò rẹ ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki nwọn ki o le gbọ́, ati ki nwọn ki o le kọ ati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ati ki nwọn ki o ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi;

13 Ati ki awọn ọmọ wọn, ti kò mọ̀, ki o le gbọ́, ki nwọn si kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun nyin, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngóke Jordani lọ lati gbà a.

Ìlànà Ìkẹyìn Tí OLUWA fún Mose

14 OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, ọjọ́ rẹ sunmọ-etile ti iwọ o kú: pè Joṣua, ki ẹ si fara nyin hàn ninu agọ́ ajọ, ki emi ki o le fi aṣẹ lé e lọwọ. Mose ati Joṣua si lọ, nwọn si fara wọn hàn ninu agọ́ ajọ.

15 OLUWA si yọ si wọn ninu agọ́ na ninu ọwọ̀n awọsanma: ọwọ̀n awọsanma na si duro loke ẹnu-ọ̀na agọ́ na.

16 OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, iwọ o sùn pẹlu awọn baba rẹ; awọn enia yi yio si dide, nwọn o si ma ṣe àgbere tọ̀ awọn oriṣa ilẹ na lẹhin, nibiti nwọn nlọ lati gbé inu wọn, nwọn o si kọ̀ mi silẹ, nwọn o si dà majẹmu mi ti mo bá wọn dá.

17 Nigbana ni ibinu mi yio rú si wọn li ọjọ́ na, emi o si kọ̀ wọn silẹ, emi o si pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, a o si jẹ wọn run, ati ibi pupọ̀ ati iyọnu ni yio bá wọn; tobẹ̃ ti nwọn o si wi li ọjọ́ na pe, Kò ha jẹ́ pe nitoriti Ọlọrun wa kò sí lãrin wa ni ibi wọnyi ṣe bá wa?

18 Emi o fi oju mi pamọ́ patapata li ọjọ́ na, nitori gbogbo ìwabuburu ti nwọn o ti hù, nitori nwọn yipada si oriṣa.

19 Njẹ nisisiyi, kọwe orin yi fun ara nyin, ki ẹ fi kọ́ awọn ọmọ Israeli: fi i si wọn li ẹnu, ki orin yi ki o le ma jẹ́ ẹrí fun mi si awọn ọmọ Israeli.

20 Nitoripe nigbati emi ba mú wọn wá si ilẹ na, ti mo bura fun awọn baba wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; ti nwọn ba si jẹ ajẹyo tán, ti nwọn si sanra; nigbana ni nwọn o yipada si oriṣa, nwọn a si ma sìn wọn, nwọn a si kẹ́gan mi, nwọn a si dà majẹmu mi.

21 Yio si ṣe, nigbati ibi pupọ̀ ati iyọnu ba bá wọn, ki orin yi ki o jẹri tì wọn bi ẹlẹri; nitoripe a ki yio gbagbé rẹ̀ lati ẹnu awọn ọmọ wọn: nitori mo mọ̀ ìro inu wọn, ti nwọn nrò, ani nisisiyi, ki emi ki o to mú wọn wá sinu ilẹ na ti mo bura si.

22 Nitorina ni Mose ṣe kọwe orin yi li ọjọ́ na gan, o si fi kọ́ awọn ọmọ Israeli.

23 O si paṣẹ fun Joṣua ọmọ Nuni, o si wipe, Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio mú awọn ọmọ Israeli lọ sinu ilẹ na ti mo bura fun wọn: Emi o si wà pẹlu rẹ.

24 O si ṣe, nigbati Mose pari kikọ ọ̀rọ ofin yi tán sinu iwé, titi nwọn fi pari,

25 Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ti nrù apoti majẹmu OLUWA, wipe,

26 Gbà iwé ofin yi, ki o si fi i sapakan apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o ma wà nibẹ̀ fun ẹrí si ọ.

27 Nitoripe mo mọ̀ ọ̀tẹ rẹ, ati lile ọrùn rẹ: kiyesi i, nigbati emi wà lãye sibẹ̀ pẹlu nyin li oni, ọlọtẹ̀ li ẹnyin ti nṣe si OLUWA; melomelo si ni lẹhin ikú mi?

28 Pè gbogbo awọn àgba ẹ̀ya nyin jọ sọdọ mi, ati awọn ijoye nyin, ki emi ki o le sọ ọ̀rọ wọnyi li etí wọn ki emi ki o si pè ọrun ati aiye jẹri tì wọn.

29 Nitori mo mọ̀ pe lẹhin ikú mi ẹnyin o bà ara nyin jẹ́ patapata, ati pe ẹnyin o yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin; ibi yio si bá nyin li ọjọ́ ikẹhin; nitoriti ẹnyin o ma ṣe buburu li oju OLUWA, lati fi iṣẹ ọwọ́ nyin mu u binu.

Orin Mose

30 Mose si sọ ọ̀rọ orin yi li etí gbogbo ijọ Israeli, titi nwọn fi pari.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34