1 BI gbolohùn-asọ̀ kan ba wà lãrin enia, ti nwọn si wá si ibi idajọ, ti nwọn si dajọ wọn; nigbana ni ki nwọn ki o fi are fun alare, ki nwọn ki o si fi ẹbi fun ẹlẹbi;
2 Yio si ṣe, bi ẹlẹbi na ba yẹ lati nà, ki onidajọ na ki o da a dọbalẹ, ki o si mu ki a nà a ni iye kan li oju on, gẹgẹ bi ìwabuburu rẹ̀.
3 Ogoji paṣan ni ki a nà a, kò gbọdọ lé: nitoripe bi o ba lé, ti o ba si fi paṣan pupọ̀ nà a jù wọnyi lọ, njẹ arakunrin rẹ yio di gigàn li oju rẹ.
4 Máṣe di akọ-malu li ẹnu nigbati o ba npakà.
5 Bi awọn arakunrin ba ngbé pọ̀, ti ọkan ninu wọn ba si kú, ti kò si lí ọmọkunrin, ki aya okú ki o máṣe ní alejò ara ode li ọkọ: arakunrin ọkọ rẹ ni ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ní i li aya, ki o si ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ fun u.
6 Yio si ṣe, akọ́bi ọmọ ti o bi ki o rọpò li orukọ arakunrin rẹ̀ ti o kú, ki orukọ rẹ̀ ki o má ba parẹ́ ni Israeli.
7 Bi ọkunrin na kò ba si fẹ́ lati mú aya arakunrin rẹ̀, njẹ ki aya arakunrin rẹ̀ ki o gòke lọ si ẹnubode tọ̀ awọn àgba lọ, ki o si wipe, Arakunrin ọkọ mi kọ̀ lati gbé orukọ arakunrin rẹ̀ ró ni Israeli, on kò fẹ́ ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ mi.
8 Nigbana ni awọn àgba ilu rẹ̀ yio pè e, nwọn a si sọ fun u: bi o ba si duro si i, ti o si wipe, Emi kò fẹ́ lati mú u;
9 Nigbana ni aya arakunrin rẹ̀ yio tọ̀ ọ wá niwaju awọn àgba na, on a si tú bàta rẹ̀ kuro li ẹsẹ̀ rẹ̀, a si tutọ si i li oju; a si dahùn, a si wipe, Bayi ni ki a ma ṣe si ọkunrin na ti kò fẹ́ ró ile arakunrin rẹ̀.
10 A o si ma pè orukọ rẹ̀ ni Israeli pe, Ile ẹniti a tú bàta rẹ̀.
11 Bi awọn ọkunrin ba mbá ara wọn jà, ti aya ọkan ba si sunmọtosi lati gbà ọkọ rẹ̀ lọwọ ẹniti o kọlù u, ti on si nawọ́ rẹ̀, ti o si di i mú li abẹ:
12 Nigbana ni ki iwọ ki o ke ọwọ́ rẹ̀ kuro, ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u.
13 Iwọ kò gbọdọ ní onirũru ìwọn ninu àpo rẹ, nla ati kekere.
14 Iwọ kò gbọdọ ní onirũru òṣuwọn ninu ile rẹ, nla ati kekere.
15 Iwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní; òṣuwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
16 Nitoripe gbogbo ẹniti nṣe wọnyi, ati gbogbo ẹniti nṣe aiṣododo, irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ.
17 Ranti ohun ti Amaleki ṣe si ọ li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti ilẹ Egipti jade wá;
18 Bi o ti pade rẹ li ọ̀na, ti o si kọlù awọn ti o kẹhin rẹ, ani gbogbo awọn ti o ṣe alailera lẹhin rẹ, nigbati ãrẹ mú ọ tán, ti agara si dá ọ; ti on kò si bẹ̀ru Ọlọrun.
19 Nitorina yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fun ọ ni isimi lọwọ gbogbo awọn ọtá rẹ yi ọ ká kiri, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati ní i, ki iwọ ki o si pa iranti Amaleki rẹ́ kuro labẹ ọrun; iwọ kò gbọdọ gbagbé.