Deu 21 YCE

Tí Ikú Ẹnìkan Bá Rúni lójú

1 BI a ba ri ẹnikan ti a pa ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati gbà a, ti o dubulẹ ni igbẹ́, ti a kò si mọ̀ ẹniti o pa a:

2 Nigbana ni ki awọn àgba rẹ ati awọn onidajọ rẹ ki o jade wá, ki nwọn ki o si wọ̀n jijìna awọn ilu ti o yi ẹniti a pa na ká.

3 Yio si ṣe, pe ilu ti o sunmọ ẹniti a pa na, ani awọn àgba ilu na ki nwọn mú ẹgbọrọ abo-malu kan, ti a kò fi ṣiṣẹ rí, ti kò si fà ninu àjaga rí;

4 Ki awọn àgba ilu na ki o mú ẹgbọrọ abo-malu na sọkalẹ wá, si afonifoji ti o ní omi ṣiṣàn kan, ti a kò ro ti a kò si gbìn, ki nwọn ki o si ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ abomalu na nibẹ̀ li afonifoji na:

5 Awọn alufa, awọn ọmọ Lefi yio si sunmọtosi; nitoripe awọn ni OLUWA Ọlọrun rẹ yàn lati ma ṣe iṣẹ-ìsin fun u, ati lati ma sure li orukọ OLUWA; nipa ọ̀rọ wọn li a o ti ma wadi ọ̀ran iyàn ati ọ̀ran lilù:

6 Ati gbogbo awọn àgba ilu nì, ti o sunmọ ẹniti a pa na, ki nwọn ki o wẹ̀ ọwọ́ wọn sori ẹgbọrọ abo-malu na, ti a ṣẹ́ li ọrùn li afonifoji nì:

7 Ki nwọn ki o si dahùn wipe, Ọwọ́ wa kò tà ẹ̀jẹ yi silẹ, bẹ̃li oju wa kò ri i.

8 OLUWA, darijì Israeli awọn enia rẹ, ti iwọ ti ràpada, ki o má si ṣe kà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ si ọrùn Israeli awọn enia rẹ. A o si dari ẹ̀jẹ na jì wọn.

9 Bẹ̃ni iwọ o si mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lãrin nyin, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA.

Àwọn Obinrin Tí Ogun Bá Kó

10 Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ si fi wọn lé ọ lọwọ, ti iwọ si dì wọn ni igbekun;

11 Ti iwọ ba si ri ninu awọn igbẹsin na arẹwà obinrin, ti iwọ si ní ifẹ́ si i, pe ki iwọ ki o ní i li aya rẹ;

12 Nigbana ni ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ; ki on ki o si fá ori rẹ̀, ki o si rẹ́ ẽkanna rẹ̀;

13 Ki o si bọ́ aṣọ igbẹsin rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ki o si joko ninu ile rẹ, ki o sọkun baba rẹ̀, ati iya rẹ̀ li oṣù kan tọ̀tọ: lẹhin ìgba na ki iwọ ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ma ṣe ọkọ rẹ̀, on a si ma ṣe aya rẹ.

14 Bi o ba si ṣe, ti on kò ba wù ọ, njẹ ki iwọ ki o jẹ ki o ma lọ si ibi ti o fẹ́; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ tà a rára li owo, iwọ kò gbọdọ lò o bi ẹrú, nitoriti iwọ ti tẹ́ ẹ logo.

Ẹ̀tọ́ Àkọ́bí ninu Ogún Baba Rẹ̀

15 Bi ọkunrin kan ba si lí aya meji, ti o fẹ́ ọkan ti o si korira ekeji, ti nwọn si bi ọmọ fun u, ati eyiti o fẹ́ ati eyiti o korira; bi akọ́bi ọmọ na ba ṣe ti ẹniti o korira;

16 Yio si ṣe, li ọjọ́ ti o ba fi awọn ọmọ rẹ̀ jogún ohun ti o ní, ki o máṣe fi ọmọ obinrin ti o fẹ́ ṣe akọ́bi ni ipò ọmọ obinrin ti o korira, ti iṣe akọ́bi:

17 Ṣugbọn ki o jẹwọ ọmọ obinrin ti o korira li akọ́bi, ni fifi ipín meji fun u ninu ohun gbogbo ti o ní: nitoripe on ni ipilẹṣẹ agbara rẹ̀; itọsi akọ́bi ni tirẹ̀.

Bí Ọmọ Ẹni Bá Ya Aláìgbọràn

18 Bi ọkunrin kan ba lí ọmọkunrin kan ti o ṣe agídi ati alaigbọran, ti kò gbà ohùn baba rẹ̀ gbọ́, tabi ohùn iya rẹ̀, ati ti nwọn nà a, ti kò si fẹ́ gbà tiwọn gbọ́:

19 Nigbana ni ki baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ki o mú u, ki nwọn ki o si fà a jade tọ̀ awọn àgba ilu rẹ̀ wá ati si ibode ibujoko rẹ̀;

20 Ki nwọn ki o si wi fun awọn àgba ilu rẹ̀ pe, Ọmọ wa yi, alagídi ati alaigbọran ni, on kò fẹ́ gbọ́ ohùn wa; ọjẹun ati ọmuti ni.

21 Ki gbogbo awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-ibi kuro lãrin nyin; gbogbo Israeli a si gbọ́, nwọn a si bẹ̀ru.

Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn

22 Bi ọkunrin kan ba dá ẹ̀ṣẹ kan ti o yẹ si ikú, ti a si pa a, ti iwọ si so o lori igi;

23 Ki okú rẹ̀ ki o máṣe gbé ori igi ni gbogbo oru, ṣugbọn bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o sin i li ọjọ́ na; nitoripe ẹni egún Ọlọrun li ẹniti a so; ki iwọ ki o má ba bà ilẹ rẹ jẹ́, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34