Deu 14 YCE

Àṣà Tí A kò Gbọdọ̀ Dá tí A bá ń Ṣọ̀fọ̀

1 ỌMỌ OLUWA Ọlọrun nyin li ẹnyin iṣe: ẹnyin kò gbọdọ̀ bù ara nyin li abẹ, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fá iwaju nyin nitori okú.

2 Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, OLUWA si ti yàn ọ lati ma ṣe enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo orilẹ-ède lọ ti mbẹ lori ilẹ.

Ẹran Tí Ó Mọ́ ati Èyí Tí Kò Mọ́

3 Iwọ kò gbọdọ jẹ ohun irira kan.

4 Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ: akọmalu, agutan, ati ewurẹ,

5 Agbọnrin, ati esuwo, ati gala, ati ewurẹ igbẹ́, ati pigargi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu.

6 Ati gbogbo ẹranko ti o là bàta-ẹsẹ̀, ti o si pinyà bàta-ẹsẹ̀ si meji, ti o si njẹ apọjẹ ninu ẹranko, eyinì ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.

7 Ṣugbọn wọnyi ni ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi ninu awọn ti o là bàta-ẹsẹ̀; bi ibakasiẹ, ati ehoro, ati garà, nitoriti nwọn njẹ apọjẹ ṣugbọn nwọn kò là bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ ni nwọn jasi fun nyin:

8 Ati ẹlẹdẹ̀, nitoriti o là bàta-ẹsẹ̀ ṣugbọn kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ ni fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn okú wọn.

9 Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo eyiti mbẹ ninu omi: gbogbo eyiti o ní lẹbẹ ti o si ní ipẹ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.

10 Ati ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ti kò si ní ipẹ́, ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ẹ; alaimọ́ ni fun nyin.

11 Gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.

12 Ṣugbọn wọnyi li awọn ti ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu wọn: idì, ati aṣa-idì, ati idì-ẹja.

13 Ati glede, ati aṣá, ati gunugun li onirũru rẹ̀;

14 Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀;

15 Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀;

16 Owiwi kekere, ati owiwi nla, ati ogbugbu;

17 Ati pelikan, ati àkala, ati ìgo;

18 Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán.

19 Ati ohun gbogbo ti nrakò ti nfò, o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: a kò gbọdọ jẹ wọn.

20 Ṣugbọn gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.

21 Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti o tikara rẹ̀ kú: iwọ le fi i fun alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki on ki o jẹ ẹ; tabi ki iwọ ki o tà a fun ajeji: nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.

Òfin nípa Ìdámẹ́wàá

22 Ki iwọ ki o dá idamẹwa gbogbo ibisi irugbìn rẹ, ti nti oko rẹ wá li ọdọdún.

23 Niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, ni ki iwọ ki o si ma jẹ idamẹwa ọkà rẹ, ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, ati ti agbo-ẹran rẹ; ki iwọ ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.

24 Bi ọ̀na na ba si jìn jù fun ọ, ti iwọ ki yio fi le rù u lọ, tabi bi ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si ba jìn jù fun ọ, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba bukún ọ:

25 Njẹ ki iwọ ki o yi i si owo, ki iwọ ki o si dì owo na li ọwọ́ rẹ, ki o si lọ si ibi na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn.

26 Ki iwọ ki o si ná owo na si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, si akọmalu, tabi agutan, tabi ọti-waini, tabi ọti lile kan, tabi si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́: ki iwọ ki o si ma jẹ nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma yọ̀, iwọ, ati awọn ara ile rẹ:

27 Ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ; iwọ kò gbọdọ kọ̀ ọ silẹ; nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ.

28 Li opin ọdún mẹta ni ki iwọ ki o mú gbogbo idamẹwa ibisi rẹ wa li ọdún na, ki iwọ ki o si gbé e kalẹ ninu ibode rẹ:

29 Ati ọmọ Lefi, nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ, yio wá, nwọn o si jẹ nwọn o si yó; ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le bukún ọ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ ti iwọ nṣe.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34