1 NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba ke awọn orilẹ-ède wọnni kuro, ilẹ ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ si rọpò wọn, ti iwọ si joko ni ilu wọn, ati ni ile wọn;
2 Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ lãrin ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní.
3 Ki iwọ ki o là ọ̀na kan fun ara rẹ, ki iwọ ki o si pín àgbegbe ilẹ rẹ si ipa mẹta, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní, ki gbogbo apania ki o ma sá sibẹ̀.
4 Eyi si ni ọ̀ran apania, ti yio ma sá sibẹ̀, ki o le yè: ẹnikẹni ti o ba ṣeṣi pa ẹnikeji rẹ̀, ti on kò korira rẹ̀ tẹlẹrí;
5 Bi nigbati enia ba wọ̀ inu igbó lọ pélu ẹnikeji rẹ̀ lati ke igi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ gbé ãke lati fi ke igi na lulẹ, ti ãke si yọ kuro ninu erú, ti o si bà ẹnikeji rẹ̀, ti on kú; ki o salọ si ọkan ninu ilu wọnni, ki o si yè:
6 Ki agbẹsan ẹ̀jẹ ki o má ba lepa apania na, nigbati ọkàn rẹ̀ gboná, ki o si lé e bá, nitoriti ọ̀na na jìn, a si pa a; nigbati o jẹ pe kò yẹ lati kú, niwọnbi on kò ti korira rẹ̀ tẹlẹrí.
7 Nitorina emi fi aṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ.
8 Ati bi OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, ti on ti bura fun awọn baba rẹ, ti o sì fun ọ ni gbogbo ilẹ na, ti o si ṣe ileri fun awọn baba rẹ;
9 Bi iwọ ba pa gbogbo ofin yi mọ́ lati ma ṣe e, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati lati ma rìn titi li ọ̀na rẹ̀; nigbana ni ki iwọ ki o fi ilu mẹta kún u si i fun ara rẹ, pẹlu mẹta wọnyi;
10 Ki a má ba tà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ninu ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki ẹ̀jẹ ki o má ba wà li ọrùn rẹ.
11 Ṣugbọn bi ọkunrin kan ba korira ẹnikeji rẹ̀, ti o si ba dè e, ti o si dide si i, ti o si lù u li alupa, ti o si kú, ti on si salọ sinu ọkan ninu ilu wọnyi:
12 Njẹ ki awọn àgba ilu rẹ̀ ki o ránni ki nwọn ki o si mú u ti ibẹ̀ wá, ki nwọn ki o si fà a lé agbẹsan ẹ̀jẹ lọwọ ki o ba le kú.
13 Ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u, ṣugbọn ki iwọ ki o mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lori Israeli, ki o si le dara fun ọ.
14 Iwọ kò gbọdọ yẹ̀ àla ẹnikeji rẹ, ti awọn ara iṣaju ti pa ni ilẹ iní rẹ ti iwọ o ní, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní.
15 Ki ẹlẹri kanṣoṣo ki o máṣe dide jẹri tì enia nitori aiṣedede kan, tabi nitori ẹ̀ṣẹ kan ninu ẹ̀ṣẹ ti o ba ṣẹ̀: li ẹnu ẹlẹri meji, tabi li ẹnu ẹlẹri mẹta, li ọ̀ran yio fẹsẹmulẹ.
16 Bi ẹlẹri eké ba dide si ọkunrin lati jẹri tì i li ohun ti kò tọ́:
17 Njẹ ki awọn ọkunrin mejeji na lãrin ẹniti ọ̀rọ iyàn na gbé wà, ki o duro niwaju OLUWA, niwaju awọn alufa ati awọn onidajọ, ti yio wà li ọjọ wọnni,
18 Ki awọn onidajọ na ki o si tọ̀sẹ rẹ̀ pẹlẹpẹlẹ: si kiyesi i bi ẹlẹri na ba ṣe ẹlẹri eké, ti o si jẹri-eké si arakunrin rẹ̀;
19 Njẹ ki ẹnyin ki o ṣe si i, bi on ti rò lati ṣe si arakunrin rẹ̀: bẹ̃ni iwọ o si mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
20 Awọn ti o kù yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù irú ìwa-buburu bẹ̃ mọ́ lãrin nyin.
21 Ki oju rẹ ki o má si ṣe ṣãnu; ẹmi fun ẹmi, oju fun oju, ehín fun ehín, ọwọ́ fun ọwọ́, ẹsẹ̀ fun ẹsẹ̀.