1 ẸNITI a fọ ni kóro, tabi ti a ke ẹ̀ya ìkọkọ rẹ̀ kuro, ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA.
2 Ọmọ-àle ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA; ani dé iran kẹwa enia rẹ̀ kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA.
3 Ọmọ Ammoni tabi ọmọ Moabu kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA; ani dé iran kẹwa enia wọn kan ki yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA lailai:
4 Nitoriti nwọn kò fi omi pẹlu onjẹ pade nyin li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti Egipti jade wá; ati nitoriti nwọn bẹ̀wẹ Balaamu ọmọ Beori ara Petori ti Mesopotamia si ọ, lati fi ọ bú.
5 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; OLUWA Ọlọrun rẹ si yi egún na pada si ibukún fun ọ, nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ fẹ́ ọ.
6 Iwọ kò gbọdọ wá alafia wọn tabi ire wọn li ọjọ́ rẹ gbogbo lailai.
7 Iwọ kò gbọdọ korira ara Edomu kan; nitoripe arakunrin rẹ ni iṣe: iwọ kò gbọdọ korira ara Egipti kan; nitoripe iwọ ti ṣe alejò ni ilẹ rẹ̀.
8 Awọn ọmọ ti a bi fun wọn yio wọ̀ inu ijọ enia OLUWA ni iran kẹta wọn.
9 Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o pa ara rẹ mọ́ kuro ninu ohun buburu gbogbo.
10 Bi ọkunrin kan ba wà ninu nyin, ti o ṣèsi di aimọ́ li oru, njẹ ki o jade lọ sẹhin ibudó, ki o máṣe wá ãrin ibudó:
11 Yio si ṣe, nigbati alẹ ba lẹ, ki on ki o fi omi wẹ̀ ara rẹ̀: nigbati õrùn ba si wọ̀, ki o ma bọ̀wá sãrin ibudó.
12 Ki iwọ ki o ní ibi kan pẹlu lẹhin ibudó, nibiti iwọ o ma jade lọ si:
13 Ki iwọ ki o si ní ìwalẹ kan pẹlu ohun-ìja rẹ; yio si ṣe, nigbati iwọ o ba gbọnsẹ lẹhin ibudó, ki iwọ ki o fi wàlẹ, ki iwọ ki o si yipada, ki o bò ohun ti o ti ara rẹ jade:
14 Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ nrìn lãrin ibudó rẹ, lati gbà ọ, ati lati fi awọn ọtá rẹ fun ọ; nitorina ki ibudó rẹ ki o jẹ́ mimọ́: ki on ki o máṣe ri ohun aimọ́ kan lọdọ rẹ, on a si pada lẹhin rẹ.
15 Iwọ kò gbọdọ fà ẹrú ti o sá lati ọdọ oluwa rẹ̀ tọ̀ ọ wá lé oluwa rẹ̀ lọwọ:
16 Ki on ki o bá ọ joko, ani lãrin nyin, ni ibi ti on o yàn ninu ọkan ni ibode rẹ, ti o wù u jù: ki iwọ ki o máṣe ni i lara.
17 Ki àgbere ki o máṣe sí ninu awọn ọmọbinrin Israeli, tabi oníwà-sodomu ninu awọn ọmọkunrin Israeli.
18 Iwọ kò gbọdọ mú owo ọ̀ya àgbere, tabi owo ajá, wá sinu ile OLUWA Ọlọrun rẹ fun ẹjẹ́kẹjẹ: nitoripe irira ni, ani awọn mejeji si OLUWA Ọlọrun rẹ.
19 Iwọ kò gbọdọ wín arakunrin rẹ fun elé; elé owo, elé onjẹ, elé ohun kan ti a wínni li elé:
20 Alejò ni ki iwọ ki o ma wín fun elé; ṣugbọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o máṣe win fun elé: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma bukún ọ ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé, ni ilẹ na nibiti iwọ nlọ lati gbà a.
21 Nigbati iwọ ba jẹ́jẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o máṣe fàsẹhin lati san a: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio bère rẹ̀ nitõtọ lọwọ rẹ; yio si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn.
22 Ṣugbọn bi iwọ ba fàsẹhin lati jẹ́jẹ, ki yio di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn.
23 Ohun ti o ba ti ète rẹ jade, ni ki iwọ ki o pamọ́, ki o si ṣe; gẹgẹ bi iwọ ti jẹ́jẹ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ani ọrẹ ifẹ́-atinuwa, ti iwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ileri.
24 Nigbati iwọ ba wọ̀ inu ọgbà-àjara ẹnikeji rẹ lọ, iwọ le jẹ eso-àjara tẹrùn; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ mú ọkan sinu ohunèlo rẹ.
25 Nigbati iwọ ba dé inu oko-ọkà ẹnikeji rẹ, njẹ ki iwọ ki o ma fi ọwọ́ rẹ yà ṣiri rẹ̀; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ yọ doje si ọkà ẹnikeji rẹ.