30 OLUWA Ọlọrun nyin ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin;
31 Ati li aginjù, nibiti iwọ ri bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbé ọ, bi ọkunrin ti igbé ọmọ rẹ̀, li ọ̀na nyin gbogbo ti ẹnyin rìn, titi ẹnyin fi dé ihinyi.
32 Sibẹ̀ ninu nkan yi ẹnyin kò gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́.
33 Ti nlọ li ọ̀na ṣaju nyin, lati wá ibi fun nyin, ti ẹnyin o pagọ́ nyin si, ninu iná li oru, lati fi ọ̀na ti ẹnyin o gbà hàn nyin, ati ninu awọsanma li ọsán.
34 OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, o si binu, o si bura, wipe,
35 Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti iran buburu yi, ki yio ri ilẹ rere na, ti mo ti bura lati fi fun awọn baba nyin,
36 Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, on ni yio ri i; on li emi o fi ilẹ na ti o tẹ̀mọlẹ fun, ati fun awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti o tẹle OLUWA lẹhin patapata.