12 Ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ nṣe itọju; oju OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lara rẹ̀ nigbagbogbo, lati ìbẹrẹ ọdún dé opin ọdún.
13 Yio si ṣe, bi ẹnyin ba fetisi ofin mi daradara, ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo, ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo,
14 Nigbana li emi o ma fun nyin li òjo ilẹ nyin li akokò rẹ̀, òjo akọ́rọ̀ ati òjo àrọkuro, ki iwọ ki o le ma kó ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ sinu ile.
15 Emi o si fi koriko sinu pápa rẹ fun ohunọ̀sin rẹ, ki iwọ ki o le jẹun ki o si yó.
16 Ẹ ma ṣọ́ ara nyin, ki a má ba tàn àiya nyin jẹ, ki ẹ má si ṣe yapa, ki ẹ si sìn ọlọrun miran, ki ẹ si ma bọ wọn;
17 Ibinu OLUWA a si rú si nyin, on a si sé ọrun, ki òjo ki o má ba sí, ati ki ilẹ ki o má ba so eso rẹ̀; ẹnyin a si run kánkán kuro ni ilẹ rere na ti OLUWA fi fun nyin.
18 Ẹ fi ọ̀rọ mi wọnyi si àiya nyin ati si ọkàn nyin, ki ẹ si so wọn mọ́ ọwọ́ nyin fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọjá-igbaju niwaju nyin.