14 Nigbana li emi o ma fun nyin li òjo ilẹ nyin li akokò rẹ̀, òjo akọ́rọ̀ ati òjo àrọkuro, ki iwọ ki o le ma kó ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ sinu ile.
15 Emi o si fi koriko sinu pápa rẹ fun ohunọ̀sin rẹ, ki iwọ ki o le jẹun ki o si yó.
16 Ẹ ma ṣọ́ ara nyin, ki a má ba tàn àiya nyin jẹ, ki ẹ má si ṣe yapa, ki ẹ si sìn ọlọrun miran, ki ẹ si ma bọ wọn;
17 Ibinu OLUWA a si rú si nyin, on a si sé ọrun, ki òjo ki o má ba sí, ati ki ilẹ ki o má ba so eso rẹ̀; ẹnyin a si run kánkán kuro ni ilẹ rere na ti OLUWA fi fun nyin.
18 Ẹ fi ọ̀rọ mi wọnyi si àiya nyin ati si ọkàn nyin, ki ẹ si so wọn mọ́ ọwọ́ nyin fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọjá-igbaju niwaju nyin.
19 Ki ẹnyin ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ nyin, ki ẹnyin ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide.
20 Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun-ọ̀na-ode rẹ: