2 Ki ẹnyin ki o si mọ̀ li oni: nitoripe awọn ọmọ nyin ti emi nsọ fun ti kò mọ̀, ti kò si ri ibawi OLUWA Ọlọrun nyin, titobi rẹ̀, ọwọ́ agbara rẹ̀, ati ninà apa rẹ̀,
3 Ati iṣẹ-àmi rẹ̀, ati iṣẹ rẹ̀, ti o ṣe lãrin Egipti, si Farao ọba Egipti, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀;
4 Ati ohun ti o ṣe si ogun Egipti, si ẹṣin wọn, ati kẹkẹ́-ogun wọn; bi o ti mu ki omi Okun Pupa bò wọn mọlẹ bi nwọn ti nlepa nyin lọ, ati bi OLUWA ti run wọn titi di oni-oloni;
5 Ati bi o ti ṣe si nyin li aginjù, titi ẹnyin fi dé ihin yi;
6 Ati bi o ti ṣe si Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ọmọ Reubeni; bi ilẹ ti yà ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, ati ara ile wọn, ati agọ́ wọn, ati ohun alãye gbogbo ti o tẹle wọn, lãrin gbogbo Israeli:
7 Ṣugbọn oju nyin ti ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA ti o ṣe.
8 Nitorina ki ẹnyin ki o pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, ki ẹnyin ki o le lagbara, ki ẹnyin ki o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki ẹ si gbà ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a;