26 Wò o, emi fi ibukún ati egún siwaju nyin li oni;
27 Ibukún, bi ẹnyin ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni:
28 Ati egún, bi ẹnyin kò ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́ ti ẹnyin ba si yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, lati ma tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ti ẹnyin kò mọ̀ rí.
29 Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, ki iwọ ki o ma sure lori òke Gerisimu, ki iwọ ki o si ma gegun lori òke Ebali.
30 Awọn kọ ha wà ni ìha keji Jordani, li ọ̀na ìwọ-õrùn, ni ilẹ awọn ara Kenaani, ti ngbé Araba ti o kọjusi Gilgali, lẹba igbó More?
31 Nitoripe ẹnyin o gòke Jordani lati wọle ati lati gbà ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin, ẹnyin o si gbà a, ẹnyin o si ma gbé inu rẹ̀.
32 Ki ẹnyin ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gbogbo ìlana ati idajọ wọnni, ti mo fi siwaju nyin li oni.