8 Nitorina ki ẹnyin ki o pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, ki ẹnyin ki o le lagbara, ki ẹnyin ki o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki ẹ si gbà ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a;
9 Ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
10 Nitoripe ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, kò dabi ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin ti jade wá, nibiti iwọ gbìn irugbìn rẹ, ti iwọ si nfi ẹsẹ̀ rẹ bomirin i, bi ọgbà ewebẹ̀:
11 Ṣugbọn ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a, ilẹ òke ati afonifoji ni, ti o si nmu omi òjo ọrun:
12 Ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ nṣe itọju; oju OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lara rẹ̀ nigbagbogbo, lati ìbẹrẹ ọdún dé opin ọdún.
13 Yio si ṣe, bi ẹnyin ba fetisi ofin mi daradara, ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo, ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo,
14 Nigbana li emi o ma fun nyin li òjo ilẹ nyin li akokò rẹ̀, òjo akọ́rọ̀ ati òjo àrọkuro, ki iwọ ki o le ma kó ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ sinu ile.