20 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ti iwọ ba si wipe, Emi o jẹ ẹran, nitoriti ọkàn rẹ nfẹ́ ẹran ijẹ; ki iwọ ki o ma jẹ ẹran, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ́.
21 Bi o ba ṣepe, ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ ba yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si, ba jìna jù fun ọ, njẹ ki iwọ ki o pa ninu ọwọ́-ẹran rẹ ati ninu agbo-ẹran rẹ, ti OLUWA fi fun ọ, bi emi ti fi aṣẹ fun o, ki iwọ ki o si ma jẹ ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́ ninu ibode rẹ.
22 Ani bi ã ti ijẹ esuro, ati agbọnrin, bẹ̃ni ki iwọ ki o ma jẹ wọn: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ yio jẹ ninu wọn bakanna.
23 Kìki ki o ṣọ́ ara rẹ gidigidi ki iwọ ki o máṣe jẹ ẹ̀jẹ: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi; iwọ kò si gbọdọ jẹ ẹmi pẹlu ẹran.
24 Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; iwọ o dà a silẹ bi omi.
25 Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; ki o le ma dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA.
26 Kìki ohun mimọ́ rẹ ti iwọ ní, ati ẹjẹ́ rẹ ni ki iwọ ki o mú, ki o si lọ si ibi ti OLUWA yio yàn: