19 Ati ohun gbogbo ti nrakò ti nfò, o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: a kò gbọdọ jẹ wọn.
20 Ṣugbọn gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
21 Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti o tikara rẹ̀ kú: iwọ le fi i fun alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki on ki o jẹ ẹ; tabi ki iwọ ki o tà a fun ajeji: nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.
22 Ki iwọ ki o dá idamẹwa gbogbo ibisi irugbìn rẹ, ti nti oko rẹ wá li ọdọdún.
23 Niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, ni ki iwọ ki o si ma jẹ idamẹwa ọkà rẹ, ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, ati ti agbo-ẹran rẹ; ki iwọ ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.
24 Bi ọ̀na na ba si jìn jù fun ọ, ti iwọ ki yio fi le rù u lọ, tabi bi ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si ba jìn jù fun ọ, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba bukún ọ:
25 Njẹ ki iwọ ki o yi i si owo, ki iwọ ki o si dì owo na li ọwọ́ rẹ, ki o si lọ si ibi na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn.