7 Bi talakà kan ba mbẹ ninu nyin, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ, ninu ibode rẹ kan, ni ilẹ rẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe mu àiya rẹ le si i, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe há ọwọ́ rẹ si talakà arakunrin rẹ:
8 Sugbọn lilà ni ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun u, ki iwọ ki o si wín i li ọ̀pọlọpọ tó fun ainí rẹ̀, li ohun ti nfẹ́.
9 Ma kiyesara ki ìro buburu kan ki o máṣe sí ninu àiya rẹ, wipe, Ọdún keje, ọdún ijọwọlọwọ sunmọtosi; oju rẹ a si buru si arakunrin rẹ talakà, ti iwọ kò si fun u ni nkan; on a si kigbe pè OLUWA nitori rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ fun ọ.
10 Ki iwọ ki o fi fun u nitõtọ, ki inu rẹ ki o máṣe bàjẹ́ nigbati iwọ ba fi fun u: nitoripe nitori nkan yi ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo iṣẹ rẹ, ati ni gbogbo ohun ti iwọ ba dá ọwọ́ rẹ lé.
11 Nitoripe talakà kò le tán ni ilẹ na: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun arakunrin rẹ, fun talakà rẹ, ati fun alainí rẹ, ninu ilẹ rẹ.
12 Ati bi a ba tà arakunrin rẹ kan fun ọ, ọkunrin Heberu, tabi obinrin Heberu, ti o si sìn ọ li ọdún mẹfa; njẹ li ọdún keje ki iwọ ki o rán a lọ kuro lọdọ rẹ li ominira.
13 Nigbati iwọ ba si nrán a lọ li ominira kuro lọdọ rẹ, iwọ kò gbọdọ jẹ ki o lọ li ọwọ́ ofo: