14 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ajọ rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ.
15 Ijọ́ meje ni ki iwọ ki o fi ṣe ajọ si OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti OLUWA yio yàn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo asunkún rẹ, ati ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, nitorina ki iwọ ki o ma yọ̀ nitõtọ.
16 Lẹ̃mẹta li ọdún ni ki gbogbo awọn ọkunrin rẹ ki o farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn; ni ajọ àkara alaiwu, ati ni ajọ ọ̀sẹ, ati ni ajọ agọ́: ki nwọn ki o má si ṣe ṣánwọ wá iwaju OLUWA:
17 Ki olukuluku ki o mú ọrẹ wá bi agbara rẹ̀ ti to, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ.
18 Awọn onidajọ ati awọn ijoye ni ki iwọ ki o fi jẹ ninu ibode rẹ gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, gẹgẹ bi ẹ̀ya rẹ: ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia na li ododo.
19 Iwọ kò gbọdọ lọ́ idajọ; iwọ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju enia: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbà ẹ̀bun; nitoripe ẹ̀bun ni ifọ́ ọlọgbọ́n li oju, on a si yi ọ̀rọ olododo po.
20 Eyiti iṣe ododo patapata ni ki iwọ ki o ma tọ̀ lẹhin, ki iwọ ki o le yè, ki iwọ ki o si ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.