13 Gbogbo enia yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki yio si gberaga mọ́.
14 Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ ba si gbà a, ti iwọ ba si joko ninu rẹ̀, ti iwọ o si wipe, Emi o fi ọba jẹ lori mi, gẹgẹ bi gbogbo awọn orilẹ-ède ti o yi mi ká;
15 Kìki ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn, ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ọkan ninu awọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ki iwọ ki o máṣe fi alejò ṣe olori rẹ, ti ki iṣe arakunrin rẹ.
16 Ṣugbọn on kò gbọdọ kó ẹṣin jọ fun ara rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe mu awọn enia pada lọ si Egipti, nitori ki o ba le kó ẹṣin jọ: nitori OLUWA ti wi fun nyin pe, Ẹnyin kò gbọdọ tun pada lọ li ọ̀na na mọ́.
17 Bẹ̃ni ki o máṣe kó obinrin jọ fun ara rẹ̀, ki àiya rẹ̀ ki o má ba yipada: bẹ̃ni ki o máṣe kó fadakà tabi wurá jọ fun ara rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ.
18 Yio si ṣe, nigbati o ba joko lori itẹ́ ijọba rẹ̀, ki on ki o si kọ iwé ofin yi sinu iwé kan fun ara rẹ̀, lati inu eyiti mbẹ niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi:
19 Yio si wà lọdọ rẹ̀, on o si ma kà ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo: ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ̀, lati ma pa gbogbo ọ̀rọ ofin yi mọ́ ati ilana wọnyi, lati ma ṣe wọn: