9 Ki iwọ ki o si tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi lọ, ati onidajọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni: ki o si bère; nwọn o si fi ọ̀rọ idajọ hàn ọ:
10 Ki iwọ ki o si ṣe bi ọ̀rọ idajọ, ti awọn ará ibi ti OLUWA yio yàn na yio fi hàn ọ; ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti nwọn kọ́ ọ:
11 Gẹgẹ bi ọ̀rọ ofin ti nwọn o kọ́ ọ, ati gẹgẹ bi idajọ ti nwọn o wi fun ọ, ni ki iwọ ki o ṣe: ki iwọ ki o máṣe yà si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi, kuro li ọ̀rọ ti nwọn o fi hàn ọ.
12 Ọkunrin na ti o ba si fi igberaga ṣe e, ti kò fẹ́ gbọ́ ti alufa na, ti o duro lati ma ṣe iṣẹ alufa nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, tabi lati gbọ́ ti onidajọ na, ani ọkunrin na yio kú: iwọ o si mú ìwabuburu kuro ni Israeli.
13 Gbogbo enia yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki yio si gberaga mọ́.
14 Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ ba si gbà a, ti iwọ ba si joko ninu rẹ̀, ti iwọ o si wipe, Emi o fi ọba jẹ lori mi, gẹgẹ bi gbogbo awọn orilẹ-ède ti o yi mi ká;
15 Kìki ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn, ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ọkan ninu awọn arakunrin rẹ ni ki iwọ ki o fi jọba lori rẹ: ki iwọ ki o máṣe fi alejò ṣe olori rẹ, ti ki iṣe arakunrin rẹ.