1 AWỌN alufa, awọn ọmọ Lefi, ani gbogbo ẹ̀ya Lefi, ki yio ní ipín tabi iní pẹlu Israeli: ki nwọn ki o ma jẹ ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ati iní rẹ̀ ni ki nwọn ki o ma jẹ.
2 Nitorina ni nwọn ki yio ṣe ni iní lãrin awọn arakunrin wọn: OLUWA ni iní wọn, bi o ti wi fun wọn.
3 Eyi ni yio si ma jẹ́ ipín awọn alufa lati ọdọ awọn enia wá, lati ọdọ awọn ti o ru ẹbọ, iba ṣe akọ-malu tabi agutan, ki nwọn ki o si fi apa fun alufa, ati ẹrẹkẹ mejeji ati àpo.
4 Akọ́so ọkà rẹ pẹlu, ati ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́rẹ irun agutan rẹ, ni ki iwọ ki o fi fun u.
5 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ li o yàn a ninu gbogbo awọn ẹ̀ya rẹ, lati ma duro ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai.