5 Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ li o yàn a ninu gbogbo awọn ẹ̀ya rẹ, lati ma duro ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai.
6 Ati bi ọmọ Lefi kan ba ti inu ibode rẹ kan wá, ni gbogbo Israeli, nibiti o gbé nṣe atipo, ti o si fi gbogbo ifẹ́ inu rẹ̀ wá si ibi ti OLUWA yio yàn;
7 Njẹ ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, bi gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Lefi, ti nduro nibẹ̀ niwaju OLUWA.
8 Ipín kanna ni ki nwọn ki o ma jẹ, làika eyiti o ní nipa tità ogún baba rẹ̀.
9 Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe kọ́ ati ṣe gẹgẹ bi ìwa-irira awọn orilẹ-ède wọnni.
10 Ki a máṣe ri ninu nyin ẹnikan ti nmu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là iná já, tabi ti nfọ̀ afọ̀ṣẹ, tabi alakiyesi-ìgba, tabi aṣefàiya, tabi ajẹ́,
11 Tabi atuju, tabi aba-iwin-gbìmọ, tabi oṣó, tabi abokulò.