13 Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi i lé ọ lọwọ, ki iwọ ki o si fi oju idà pa gbogbo ọkunrin ti mbẹ ninu rẹ̀:
14 Ṣugbọn awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ ati ohun-ọ̀sin, ati ohun gbogbo ti mbẹ ni ilu na, ani gbogbo ikogun rẹ̀, ni ki iwọ ki o kó fun ara rẹ; ki iwọ ki o si ma jẹ ikogun awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
15 Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo ilu ti o jìna rére si ọ, ti ki iṣe ninu ilu awọn orilẹ-ède wọnyi.
16 Ṣugbọn ninu ilu awọn enia wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki iwọ ki o máṣe da ohun kan si ti o nmí:
17 Ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn run patapata; awọn ọmọ Hitti, ati awọn Amori, awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ:
18 Ki nwọn ki o má ba kọ́ nyin lati ma ṣe bi gbogbo iṣẹ-irira wọn, ti nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; ẹnyin a si ṣẹ̀ bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin.
19 Nigbati iwọ ba dótì ilu kan pẹ titi, lati bá a jà lati kó o, ki iwọ ki o máṣe run igi tutù rẹ̀ ni yiyọ ãke tì wọn; nitoripe iwọ le ma jẹ ninu wọn, iwọ kò si gbọdọ ke wọn lulẹ; nitori igi igbẹ́ ha ṣe enia bi, ti iwọ o ma dòtí i?