4 Nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ni mbá nyin lọ, lati bá awọn ọtá nyin jà fun nyin, lati gbà nyin là.
5 Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia, pe, Ọkunrin wo li o kọ ile titun, ti kò ti ikó si i? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba kó si i.
6 Ati ọkunrin wo li o gbìn ọgbà-àjara, ti kò si ti ijẹ ninu rẹ̀? jẹ ki on pẹlu ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba jẹ ẹ.
7 Ati ọkunrin wo li o fẹ́ iyawo, ti kò ti igbé e? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba gbé e.
8 Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia na si i, ki nwọn ki o si wipe, Ọkunrin wo li o wà ti o bẹ̀ru ti o si nṣojo? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki àiya awọn arakunrin rẹ̀ ki o má ba ṣojo pẹlu bi àiya tirẹ̀.
9 Yio si ṣe, nigbati awọn olori-ogun ba pari ọ̀rọ sisọ fun awọn enia tán, ki nwọn ki o si fi awọn balogun jẹ lori awọn enia na.
10 Nigbati iwọ ba sunmọ ilu kan lati bá a jà, nigbana ni ki iwọ ki o fi alafia lọ̀ ọ.