16 Ki baba ọmọbinrin na ki o si wi fun awọn àgba na pe, Emi fi ọmọbinrin mi fun ọkunrin yi li aya, o si korira rẹ̀;
17 Si kiyesi i, o si kà ọ̀ran si i lọrùn, wipe, Emi kò bá ọmọbinrin rẹ ni wundia; bẹ̃ni wọnyi ni àmi wundia ọmọbinrin mi. Ki nwọn ki o si nà aṣọ na niwaju awọn àgba ilu.
18 Ki awọn àgba ilu na ki o si mú ọkunrin na ki nwọn ki o si nà a;
19 Ki nwọn ki o si bù ọgọrun ṣekeli fadakà fun u, ki nwọn ki o si fi i fun baba ọmọbinrin na, nitoriti o bà orukọ wundia kan ni Israeli jẹ́: ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀; ki o máṣe kọ̀ ọ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.
20 Ṣugbọn bi ohun na ba ṣe otitọ, ti a kò ba si ri àmi wundia ọmọbinrin na:
21 Nigbana ni ki nwọn ki o mú ọmọbinrin na wá si ẹnu-ọ̀na ile baba rẹ̀, ki awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: nitoriti o hù ìwa-buburu ni Israeli, ni ṣiṣe àgbere ninu ile baba rẹ̀: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
22 Bi a ba mú ọkunrin kan ti o bá obinrin kan dàpọ, ti a gbé ni iyawo fun ọkọ, njẹ ki awọn mejeji ki o kú, ati ọkunrin ti o bá obinrin na dàpo, ati obinrin na: bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ìwa-buburu kuro ni Israeli.